SPLITTING VERBS Flashcards
- Kọ ( ) sílẹ̀ - Ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀
- Pa ( ) tì - A ti pa iṣẹ́ yẹn ti
- Ja ( ) jù sílẹ̀ - Ó ja wa jù sílẹ̀
Abandon
- He abandoned them.
- We have abandoned the work.
- He abandoned us.
Dá ( ) dúró - Ẹ má dá mi dúró
Delay - Do not delay me.
Gé ( ) kúrú - Wọ́n gé ọ̀rọ̀ náà kúrú
Abbreviate - She abbreviated the words.
Fà ( ) mu - Aṣọ mi fa epo mu .
Absolve - My cloth absolved the palm oil
Sọ ( ) dọmọ - Wọ́n ti sọ ọ́ dọmọ
Adopt - They have adopted him.
Ṣe ( ) lọ́ṣọ̀ọ́ - À ń ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́
Adorn - We are adorning the house.
Gba ( ) ní ìmọ̀nràn - Ó gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn
Advise - She advised them.
Gbé ( ) sálọ - Ó gbé ọmọ mẹ́ta sálọ
- Jí ( ) gbé - Wọ́n jí ààrẹ gbé
Abduct
1. He abducted three children.
- They abducted the president.
Tún ( ) ṣe - Ẹ bá mi tún aṣọ mi ṣe
Adjust - Help me adjust my dress.
Gbà ( ) wọlé -Ifásitì Ìbàdàn gbà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tuntun wọlé
Admit - The University of Ibadan has admitted new students.
Yà ( ) lénú - Ó yà wá lẹ́nu
Amaze - He amazed us.
Fà ( ) mọ́ra - Ilée wọn fa wá mọ́ra
Attracts - Her house attracts us.
fí ( ) Kún - Ẹ fi owó díẹ̀ kún owóo wọn
Add - Add a little money to their money.
Dá obj lóhùn - Kò dá mi lóhùn
Answer - He did not answer me.
Ya ( ) lẹ́nu - Ó yà wá lẹ́nu
Astonish - He astonished us.
Dàn ( ) wò - A ò gbọdọ̀ dan an wò
Attempt - We must not attempt it.
Sọ̀rọ ( ) lẹ́yìn - Wọ́n ń sọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn
Back-bite - They are back-biting me.
- Bá ( ) rẹ́ - Ó ǹ bá ọ̀ṣìṣẹ́ tuntun rẹ́
- Bá ( ) ṣe ọ̀rẹ́ - Túnjí ń bá Ṣọlá ṣe ọ̀rẹ́
Befriend
- She is befriending the new worker.
- Tunji befriends Sola
Rú ( ) lójú - Ọ̀rọ̀ náà rú mi lójú
Baffle - - The issue baffled me.
Gba ( ) gbọ́ - Ẹ ní láti gbà wá gbọ́
Believe - You have to believe us.
Gé ( ) jẹ - Ajá gé ọmọ náà jẹ
Bite - The dog bit the child.
Dá ( ) lẹ́bi - Wọ́n dá wa lébi
Blame - They blamed us.
Mú ( ) rẹwá - Wọ́n ń mu ilée wọn rẹwà
- Ṣe ( ) lọ́ṣọ̀ọ́ - A gbọdọ̀ ṣẹ ilée wa lọ́ṣọ̀ọ́
Beautify
- They are beautifying their house.
- We must beautify our house,
Dà ( ) lẹ́bí - Má dà mi lẹ́bi
Blame - Do not blame me.
Bá ( ) yọ̀ - Ẹ ma bá wa yọ
Celebrate - You will celebrate with me.
Mú ( ) wá (light object) - Mú ṣíbí wá
- Gbé ( ) wá (heavy) - Bá mi gbé oúnjẹ mi wá
Bring
1. Bring a spoon.
- Help me bring my food.
Ọwọ́ ( ) dí - Ọwọ́ọ wọn dí
Busy - They are busy.
Yẹ̀ ( ) wò - Ẹ yẹ̀ ẹ́ wò
Check - Check it.
Fi ( ) wé - Má fi mi wé wọn rárá
Compare - Do not compare me with them at all.
Pa ( ) dé - Ẹ pa ilẹ̀kùn dé
Close - Close the door.
kí ( ) kú oríire - Wọ́n kí wa kú oríire
Congratulate - They will congratulate us.
Tù ( ) nínú - Ọlọ́run á tù yín nínú
Console - God will console you.
Bẹ̀ ( ) wò - Wọ́n lọ bẹ́ dọ́kítà wò
Consult - She went to consult the doctor.
Rú ( ) lójú - Má rú mi lójú
Confuse - Do not confuse me.
Ṣe ( ) lọ́sọ̀ọ́ - À ń ṣe ilée wa lọ́ṣọ̀ọ́
Decorate - We are decorating our house.
Dá ( ) dúró - Ẹ má da mi dúró
Delay - Do not delay me.
Bà ( ) jẹ́ - Àwọn ọmọ ti bá aago mi jẹ́
- Pa obj run - Ẹ ò gbọdọ̀ pa àṣà Yorùbá run
Destroy
1. The children have destroyed my watch.
- You must not destroy the Yoruba culture.
Bá obj jẹun - A ma bá wọn jẹun .
Dine - We will dine with them
Ba ( ) lójú jẹ́ - Ẹ ò gbọ́dọ̀ bà wá lọ́jú jẹ
- Já ( ) kulẹ̀ - Wọ́n já wọn kulẹ̀
Disappoint - You must not disappoint us.
- They disappointed them.
Dà ( ) láàmú - Má dà mí láàmu
- Yọ ( ) lẹ́nu - Wọ́n ń yọ wá lẹ́nú
Disturb - Do not disturb me.
- They are disturbing us.
Mú ( ) sílẹ̀ - Bá mi mú ìwé yẹn sílẹ̀
Drop - Help me drop the book.
Já ( ) jù sílẹ̀ - Ó já wọn jù sílẹ̀
Dump - He dumped her.
Pa ( ) láró - À ń pa aṣọ wa láró
Dye - We are dying our fabrics.
Ró ( ) lágbára - Ìjọba ró wọn lágbára
Empower - The government empowered them.
Gbà ( ) níyànjú - A lè gbà wọ́n níyànjú
Encourage - I will encourage them.
Tún ( ) ṣe - Mo ti tún ọkọ mi ṣe
Fix - I have fixed my car.
Mú ( ) mọ́ra - Ẹ ní láti mu u mọ́ra
Endure - You have to endure it.
Wò ( ) sàn - Ọlọ́run á wò yín sàn
- Mú ( ) lára dá - Ọlọ́run á mu yín lára dá
Heal - God will heal you.
- God will heal you.
Fi ( ) kọ́ - Fi aṣọ yẹn kọ́
Hang - Hang that cloth.
Ràn ( ) lọ́wọ́ - Kí olúwa ràn yín lọ́wọ́
Help - May God help you.
Fi ( ) pamọ́ - Ó fi ara pamọ́
Hide - He hid himself.
Dí ( ) lọ́wọ́ - Ò ń di mi lọ́wọ́
Hinder - You are hindering me.
fi ( ) pamọ́ - Bá mi fi owó yìí pamọ
Keep - Help me keep this money.
Dì ( ) mú - Dì mi mú
Di ( ) mú - Di ọwọ́ ẹ mú
Hold - Hold me.
Hold - Hold his hand.
Ta ( ) nípàá - Ó ta mi nípàá
Kick - He kicked me.
Tẹ́ ( ) lọ́rùn - Ó ṣòro láti tẹ-ẹ tọ́rùn
Please - It is hard to please her
Dà ( ) nù - Ó da oúnjẹ mi nù
Pour - He poured out my food.
fún ( ) lẹ́ṣẹ̀ẹ́ - Ó fun-un lẹ́ṣẹ̀ẹ́
Punch - He punched him.
fí obj sí - Níbo ni ẹ fi owó mi sí
Put - Where did you put my money?
Gbé ( ) sókè - Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè
Raise - Raise your hands.
Dá ( ) mọ́ - Mo lè dá wọn mọ̀
Recognize - I can recognize them.
Dín ( ) kù - Ẹ dín oúnjẹ mi kù
Reduce - Reduce my food. (Formal, two or more people)
Tún ( ) ṣe - Bàbá ń tún ọkọ̀ wọn ṣe
Repair - Father is repairing his car.
Rán ( ) létí - A máa rán wọn létí
Remind -We will remind them.
Dá ( ) lóhùn - Kò dá wọn lóhùn rárá
Reply - She did not reply at all.
Yọ ( ) níṣẹ́ - Ó ti yọ wọ́n níṣẹ́
Sack - He has sacked them.
Tẹ ( ) lọ́rùn - A ò lè tẹ́ wọn lọ́rùn
Satisfy - We cannot satisfy them.
Ẹ̀rù ( ) bá - Ẹ̀rù wọn ń bà mí
Scare - I am scared of her.
Dà ( ) rú - Wọ́n da yàrá mi rú
- Tú ( ) ká - Ó ń tú ẹrù mi ká
Scatter - They scattered my room.
- She is scattering my luggage.
Ba ( ) jẹ́ - Ẹ má ba àwọn ọmọ yín jẹ
Spoil - Do not spoil your child.
Rán ( ) níṣẹ́ - Mo fẹ́ ran ẹ níṣẹ́
- Fi obj ránṣẹ́ - Wọ́n ti fi owó ránṣẹ́ (object)
Send
- I want to send you on errands.
- She has sent the money.
Yọ ( ) kúrò - Ó yọ Dollar mẹ́wàá kúrò nínú owó mi
Subtract - She subtracted ten dollars from my money.
Tì ( ) lẹ́yìn - Wọ́n ti wà léyìn
Support - They supported us.
Yà ( ) lẹ́nu - Ọmọ yẹn yà wá lẹ́nu
Surprise - That child surprised us.
Dà ( ) lójú - Ó dá mi lójú -
Sure - I am sure.
Literal meaning - It sure me.
Tọ́ ( ) wò - Mo ti tọ-ọ wò
Taste - I have tasted it.
Gbé ( ) mi - Ó gbé egungun mi
Swallow - He swallowed the bone.
Jù ( ) nù - Àbúrò mi ju bàtà mi nù
Throw away - My younger sibling threw away my shoes.
Tú ( ) sí - Ó tú ìwé ẹ̀ sí èdè Faranse
- Túmọ̀ ( ) sí - Ṣé ẹ lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí èdè Yorùbá
Translate - He translated his book into French.
- Can you translate this word to Yoruba.
Bẹ̀ ( ) wò - Wọ́n bẹ̀ mí wò ní àná
Visit - They visited me yesterday.
kí ( ) káàbọ̀ - Wọ́n kí mi káàbọ̀
Welcome - They welcomed me.
Ṣi ( ) pè - Ó ṣí orúkọ mi pè
Mispronounce - She mispronounced my name.
Ṣi ( ) lò - Wọ́n ṣi owó náà lò
ii. Lo ( ) ní ìlòkùlò - Wọ́n lò ipò wọn ní ìlòkùlò
Misuse - They misused the money.
Misuse - They misused their position.
Ṣi ( ) lọ́nà - Ó ṣì wọn lọ́nà nípa iṣẹ́ náà
Misinform - She misinformed them about the job.
Fi ( ) ṣe ẹ̀sín - Ó fi mí ṣe ẹ̀sín.
ii. Fi ( ) ṣe ẹlẹ́yà - Wọ́n fi ọ̀rẹ́ mi ṣe ẹlẹ́yà.
Mock - He/She mocked me.
Mock - They mocked my friend.
Ṣì ( ) gbọ́ - Ó ṣi ọ̀rọ̀ mi gbọ́
misheard - He/She misheard my words.