ALL NOUNS Flashcards
Eranko - Mi ò fẹ́ràn ẹranko
Animal - I do not like animals
Ẹfọ̀n - Mo rí ẹfọ̀n ní ọgbà ẹranko
African Buffalo - I saw a buffalo at the zoo
Àrígiṣẹ́gi - Àrígiṣẹ́gi máa ń ṣẹ́ igi
Bagworm moth - The bagworm moth collects sticks.
Ìlábùrù - Ìlábùrù ò jọ ìnàkí
Baboon - The baboon doesn’t look like a gorilla.
Àdan - Àwọn àdán máa ń fò ní ìrọ̀lẹ́
Bat - The bats usually fly in the evening
Ẹyé - Ẹyẹ ń kọrin
Bird - The bird sings
Ìbákà - Ṣé o mọ ẹyẹ ìbákà tí o bá rí-i
Canary bird - Do you know the canary bird if you see it?
Àlùkò - Mo pa ẹyẹ àlùkò
Cardinal bird - I killed a cardinal bird
Lékeléke - Àwọn eyẹ lékeléke máa ń tèlé àwọn màlúù
Cattle egret - The cattle egrets always follow the cows
Adìyẹ - Mo ti bọ adìyẹ
Chicken - I have boiled the chicken
Àkùkọ - Àkùkọ ń kọ
Cock - The cock crows
Akọ̀ - Bàbá Túnjí pa ẹyẹ akọ̀
Crane bird - Tunji’s father killed a crane bird
Àdàbà - Mo fẹ́ràn ẹye àdàbà
Dove - I like doves.
Pẹpẹ́yẹ́ - Mo jẹ ẹran pẹ́pẹ́yẹ́
Duck - I ate duck meat.
Awó - Mo jẹ awó
Guinea fowl - I ate guinea fowl.
Agbe - Mo ra agbe
Great Blue Turaco - I bought a great blue turaco.
Àkọ̀ - Ẹyẹ àkọ̀ rẹwà
Grey Heron - The grey heron is beautiful
Ẹyẹ Afìyẹ́lùlù - Ẹyẹ Afìyẹ́lùlù ń fìyẹ́ lùlù
Hummingbird - The hummingbird is using its feathers to drum.
Òdèré-kókò - Òdèré-kókò ń kọrin
Mourning dove - The morning dove is singing
Ìròsùn - Ẹyẹ Ìròsùn méjì bà lórí igi
Orange Bishop - Two orange Bishops perched on a tree.
Ọṣìn - Ọṣìn ń fò lójú ọ̀rún
Osprey - The osprey is flying in the sky.
Ògòngò - Ògòngò baba ẹyẹ
Ostrich - The ostrich is the father of birds.
Òwìwí - Mi ò f́ẹ́ràn òwìwí
Owl - I don’t like owls.
Ayékòótọ́ - Ẹyẹ Ayékòótọ́ máa ń rojọ́
Parrot - The parrot always talks.
Àparò - Bàbá pa àparò mẹ́ta ní oko
Partridge - Father killed three partridges on the farm
Ọ̀kín - Adé orí ọ̀kín rẹwà
Peacock - The crown on the peacock is beautiful.
Kannakánná - Mi ò mọ Kannakánná
Pied Crow - I don’t know the Pied Crow bird.
Ẹyẹlé - Mo ní ẹyẹlé mẹ́ta
Pigeon - I have three pigeon
Ìwò - Tọ́lá ra ẹyẹ ìwò dúdú ní àná
Raven - Tola bought three black raven yesterday.
Tío-tío - Ṣé ẹ fẹ́ ẹyẹ tío-tío
Shrike - Do you want a shrike bird?
Tòlótòló - Mo fẹ́ràn láti jẹ Tòlótòló
Turkey - I like to eat turkey.
Igúnnugún/Igún - Ígún máa ń jẹ òkú
Vulture - The vultures eats corpses.
Ẹ̀gà - Ẹyẹ ẹ̀gà máa ń kọ ilée wọn
Weaver - The weavers build their nests.
Àkókó - Ẹyẹ Àkókó máa ń gbé igi
Woodpecker - The woodpecker is pecking the tree
Ológbò - Mo ní ológbò dúdú mẹ́ta
Cat - I have three black cats.
Ràkúnmí - Ó ra Ràkúnmí láti Kano
Camel - He bought a camel from Kano
Ọrùn-ẹsẹ̀ - Ọrùn-ẹsẹ̀ ẹ rọ́
Ankle - His ankle sprained
Apá - Ó na apa ẹ̀
Arm - She stretched her arm
Abíyá - Abíyá ẹ̀ ń rùn
Armpit - Her armpit smells
Ẹ̀yìn - Ẹ̀yìn ń ro màmá
Back - Mummy’s back hurts
Irùngbọ̀n - ó ní irùngbọ̀n púpa
Beard - He has a red beard
Ẹ̀jẹ̀ - Mi ò lè mu ẹ̀jẹ̀
Blood - I cannot drink blood
Ara - Ara wọn ò yá
Body - He is sick
Ọyàn - Lọlá ní ọyàn kékeré
Breast - Sola’s breast size is small
Ìdí - Ó ní ìdí ńlá
Buttocks - She has prominent curves (buttocks)
Àyà - Àyà mi ò já
Chest - I am not scared
Literal meaning - My chest is not cutting
Ẹ̀ẹ̀kẹ́ - Ẹ̀ẹ̀kẹ́ ẹ̀ tóbí
Cheek - She has big cheeks
Àgbọ̀n - Eéwo wà ní àgbọ̀ ẹ̀
Chin - There is a boil on his chin
Etí - Etí mi ò di
Ear - I am not deaf
Literal meaning - My ears are not blocked
Ìgunpá - ó fi ìgunpá ẹ̀ gbá mi
Elbow - He hit me with his elbow
Ojú - Ojú ẹ ò fọ́
Eye - She is not blind
Literal meaning - Her eyes are not broken
Irun ojú - Kò ní irun ojú
Eyebrow - She doesn’t have eyebrows
Ìpéǹpéjú - Ìpéǹpéjú mi ń yún mi
eyelashes - My eyelashes itch
Ojú - Ó ń wo ojú mi
Face - She looks at my face
Àtẹ́lẹsẹ̀ - Àtẹ́lẹṣẹ̀ ẹ̀ dọ̀tí
Feet - His feet are dirty
Ìka-ọwọ́ - Ìka-ọwọ́ ò dọ́gba
Finger - Fingers are not equal
Èékánná - Mò fẹ́ gé èékánná mi
Fingernail - I want to cut my nails
Ọkàn - Ọkàn mí balẹ̀
Heart - My heart is at peace
Literal meaning - My heart is calm
Irun - Mò ń fọ irun mi
Hair - I am washing my hair
Ọwọ́ - Fọ ọwọ́ ẹ kí o tó jẹun
Hand - wash your hand before you eat
Orí - Orí ń fọ́ mi
Head - I have a headache
Literal meaning - My head breaks
Gìgésẹ̀ - Fọ gìgésẹ̀ ẹ
Heel - Wash your heels
Orúnkún - Ó ń fí orúnkún rá
Knee - He crawls on his knees
Kókó-ìka - Ó fi kókó-ìka ẹ̀ gbá mi
Knuckles - He hit me with his knuckles
Ẹsẹ̀ - Ẹsẹ̀ ń dùn wọ́n
Leg - His leg hurts
Ètè - Ètè mí gbẹ
Lip - My lips are dry
Ẹnu - Pa ẹnu ẹ mọ́
Mouth - Close your mouth
Ìdodo - Mo ní ìdodo kékeré
Navel - I have a small navel
Ọrùn - Ọrùn ń ro wọ́n
Neck - Her neck aches
Imú - A máa ń fi imú gbóòórùn
Nose - We use our nose to smell
Ihò-imú - Ó nu ihò-imú
Nostril - She cleaned her nostrils
Àtẹ́lẹwọ́ - Jẹ́ ki n wo àtẹ́lẹwọ́ ẹ
Palm - Let me see your palm
Apá - Mi ò ní àpá
Scar - I don’t have a scar
Èjìká - Sinmi lé èjìká mi
Shoulder - Rest on my shoulder
Ikùn - Ikùn ń dun Adé
Stomach - Ade’s stomach hurts
Eyín - Mó ń fọ eyín mi
Teeth - I am brushing my teeth
Itan - Mo ra itan málùú fún ọbẹ̀
Thigh - I bought a cow thigh for soup
Àtànpàkò - Fi àtànpàkò ẹ hàn mí
Thumb - Show me your thumb
Ìka-ẹsẹ̀ - Wọ́n ní ìka-ẹsẹ̀ kékeré
Toe - He have little toes
Ahọn - Ó yọ ahọn síta
He stuck out the tongue
Ìbàdí - Má wo ìbàdí ẹ
Waist - Don’t look at her waist
Ọrún-ọwọ́ - O wọ aago sí ọrùn-ọwọ́
Wrist - He had a watch on his wrist
Ṣòkòtò bóńfò - Ó wọ ṣòkòtò bóńfò
Ankle pants - He wore an ankle pants
Bàǹtẹ́ - Ó so bàǹtẹ́ mọ ara
Apron - She tied an apron on her body
Bùbá - Mo ra bùbá méta
Blouse - I bought three blouses
Fìlà - Ó dé fìlà
Cap - He wore a cap
Aṣọ - Mo ní aṣọ púpọ̀
Cloth - I have a lot of clothes
Ìgò-ojú - Mò ń lo ìgò-ojú
Eyeglasses - I use eyeglasses
Agbádá - Ó ní agbádá púpọ̀
Flowing robe - He has a lot flowing robes
Kaba - Mo ni kaba dúdú
Gown - I have a black gown
Ṣòkòtò Gígùn - Mo fẹ́ wọ ṣòkòtò gígùn
Full-length pants - I want to wear a full-length pants
Gèlè - Mò ń we gèlè
Head tie - I am wrapping a head tie
Ṣòkòtò - Mi ò fẹ́ràn láti wọ ṣòkòtò
Pants - I don’t like to wear pants
Àpamọ́wọ́ - Ó sọ àpamọ́wọ́ ẹ nù
Purse - She lost her purse
Ìborùn - Ó ní láti lo ìborùn
Shawl - You have to use a shawl
Ẹ̀wù - Wọ ẹ̀wù ẹ
Shirt - Put on your shirt
Bàtà - Mo ra bàtà tuntun
Shoe - I bought new shoes
Ṣòkòtò péńpé - Ó wọ ṣòkòtò péńpé
Short - She wore shorts
Yẹ̀rì - Ó wọ yẹ̀rì dúdú
Skirt - She wore a black skirt
Ìbọ̀sẹ̀ - Wọ ìbọ̀sẹ̀ ẹ kí o tó jáde
Socks - Wear your socks before you go out
Àwọ̀tẹ́lẹ̀ - Kò wọ àwọ̀tẹ́lẹ̀
Underwear - She didn’t wear underwear
Ìró - Mi ò tí ì ró ìró rí
Wrapper - I have never wrapped a wrapper
Ẹ̀wà - A fẹ́ se ẹ̀wà
Beans - We want to cook beans
Gbẹ̀gìrì - Mi ò fẹ́ràn gbẹ̀kìrì
Bean soup - I do not like bean soup
Àkàrà òyìnbó - Mo jẹ àkàrà òyìnbó ní ọjọ́-ìbí mi
Cake - I ate cake on my birthday
Kókò - Mò ń dín kókò
Cocoyam - I am frying cocoyam
Àgbàdo - Mò fẹ́ se àgbàdo
Corn - I want to cook corn
Ẹ̀kọ - Mo jẹ ẹ̀ko ní àná
Cornmeal - I ate cornmeal yesterday
Ẹyin - Mo fọ́ ẹyin méfà
Egg - I broke six eggs
Ẹja - Mo din ẹja mẹ́ta
Fish - I fried three fish
Oúnjẹ - Oúnjẹ wo lo fẹ́ràn jù
Food - What is your favourite food
Ẹyin díndín - Mo jẹ ẹyin díndín àti búrẹ́dì
Fried egg - I ate fried eggs and bread
Dòdò - Mo fẹ́ràn dòdò
Fried plantain - I like fried plantain
Dùǹdún - Mo jẹ dùǹdún
Fried yam - I ate fried yam
Èso - Mo ní láti jẹ èso
Fruit - I have to eat fruits
Ọ̀gẹ̀dẹ̀ - Mo ra ọ̀gẹ̀gẹ̀
Banana/plantain - I bought banana/plantain
Ọsàn-wẹ́wẹ́ - Mo nílò ọsàn wẹ́wẹ́
Lemon - I need lemon
Òroǹbó - Mo ra òroǹbó
Lime - I bought lime
Ọsàn - Mo fẹ́ràn láti mu ọsàn
Orange - I like to drink orange
Ìbẹ́pe - Mò ń jẹ ìbẹpẹ
Papaya - I am eating papaya